Genesis 49:29-32

Ikú Jakọbu

29Nígbà náà ni ó fún wọn ní àwọn ìlànà yìí, “Ọjọ́ ikú mi kù fẹ́ẹ́rẹ́. Kí ẹ sin mí sí ibojì pẹ̀lú àwọn baba mi ní inú àpáta ní ilẹ̀ Hiti ará Efroni. 30 aIhò àpáta tí ó wà ní ilẹ̀ Makpela, nítòsí Mamre ní Kenaani, èyí tí Abrahamu rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìsìnkú lọ́wọ́ Efroni ará Hiti pẹ̀lú ilẹ̀ rẹ̀. 31 bNíbẹ̀ ni a sin Abrahamu àti aya rẹ̀ Sara sí, níbẹ̀ ni a sin Isaaki àti Rebeka aya rẹ̀ sí, níbẹ̀ sì ni mo sìnkú Lea sí. 32Ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni a rà lọ́wọ́ ará Hiti.”

Copyright information for YorBMYO